PARTNERSHIP IN YORUBA LANGUAGE | ÀJỌṢE
PARTNERSHIP IN YORUBA LANGUAGE | ÀJỌṢE
*PARTNERSHIP # ÀJỌṢE*
Oríkì: A lè ki àjọṣe gẹ́gẹ́ bíi irú ìgbékalẹ̀ òwò kan nínú èyí tí ẹni méjì sí ogún ti ṣàdéhùn lábẹ́ òfin láti dásílẹ̀ àti láti darí ìgbékalẹ̀ òwò kan pẹ̀lú àfojúsùn kan ṣoṣo láti jèrè.
A aṣ́abà máa ń ṣẹ̀dá àjọṣé láti ọwọ́ ẹgbẹ́ ẹni méjì sí ogun, lawọn tí wọ́n ti ṣàdéhùn, lọ́pọ̀ ìgbà lábẹ́ òfin, láti tu àwọn ọrọ̀ wọn jọ tàbí àkọ́mọ̀ wọn tàbí méjèèjì àti láti ṣe ìdásílẹ̀ àdáwọ́lé òwò kan. Àwọn tó kópa nínú àdéhùn àjọṣe ni à ń pè ní alájọṣe. Awọn alájọṣe máa ń jùmọ pín èrè, àdánù àti ewú inú òwò náà. Nígbà tí àwọn alájọṣe bá kópa nínú àdáwọ́lé iṣẹ́ báńkì, iye ẹni tí a nílò lábẹ́ òfin wà láàárín méjì sí mẹ́wàá. Díẹ̀ lára àpẹẹrẹ àjọṣe ní Nàìjíríà ni Gani Fawẹhinmi and Co. (Law chamber), Diya Fatimilehin and Co. (estate firm).
*Advantages of partnership # Àwọn àǹfààní àjọṣe*
(1) Sufficient capital # Ojúowó tító: Àjọṣe ní àwọn ọrọ owónàá púpọ̀ ju ìjólùni ẹlẹ́nìkan nítorí pé àwọn ènìyàn púpọ̀ síi ló ń kópa, látàrí bẹ́ẹ̀ ojúowó púpọ̀ síi ni yóò di kíkójọ nípasẹ ìdáwó àwọn alájọṣe.
(2) Increase in production # Àlékún ìgbéjáde
(3) Joint decision making # Ìpinnu àjùmọ̀ṣe: Àwọn àbọ̀ dídára síi ló máa ń jáde nígbà tí àwọn alájọṣe méjì tàbí jù bẹ̀ bá pa ìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n sì jùmọ̀ ṣe àwọn ìpinnu fún àdáwọ́lé náà.
(4) There is privacy # Ìdákọ́ńkọ́ máa ń wà: Ìdákọ́ńkọ́ máa ń wà nítorí pé àwọn alájọṣe kò sí lábẹ́ kàn-ńpá òfin láti ṣe ìtẹ̀jáde àwọn àsùnwọ̀n olọ́dọọdún wọn fún ìṣamúlò aráàlú.
(5) Better management # Ìdari dídára síi: Nípa kíkópapọ̀ àwọn àkọ́mọ̀ àti mímọ̀ọ́ṣe, àwọn òwò àjọṣe a sábà máa ṣe í darí ju òwò ẹlẹ́nìkan.
(6) Sharing of risks and liabilities # Pínpín ewu àti àtijẹ̀bi: Àwọn alájọṣe máa ń jùmọ̀ pín ewu àti àtijẹ̀bi, tí èyi sì máa ń mú àdínkù bá àjàgà olúkúlùkù.
(7) Better chance of continuity # Àǹfààní dídára síi láti tẹ̀síwájú: Àǹfààní dídárá síi wà fún ìtẹ̀síwájú nítorí pé ikú tàbí ìkúrò alájọṣe kan lè má yọrí sí òpin òwò náà.
(8) No legal formalities required # A kò nílò ọ̀fíntótó òfin: Láti ṣe ìdásílẹ̀ àjọṣe, a kò nílò ìrínàjò gbòógì fún ìgbékàlẹ̀, kò rí bíi ti kọ́ńpìnnì.
(9) Increased efficiency # Ìjáfáfá púpọ̀ síi
(10) Specialisation in management # Ìlákànṣe nínú ìdarí: Àlàkalẹ̀ pínpín làálàá máa ń di mímúlò nínú ètò onípòjipò onídarí àti oníṣakóso ti òwò náà.
(11) Greater possibility of expansion # Àtiṣeéṣe ìgbèrú gíga síi: Àtiṣeéṣe ìgbèrú wà nípa lílo àfikún ojúowó tí a rí gbà lọ́wọ́ àwọn alájọṣe tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń darapọ̀.
(12) Loan facilities # Ìrọ̀rùn ẹ̀yáwó: Àjọṣe lè rí ẹ̀yáwó gbà nírọ̀rùn lọ́dọ àwọn ayánilówó níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ṣe ni àwọn alájọṣe jùmọ̀ ni àtijẹ̀bi. A lè lo ẹ̀yáwó náà fún ìgbèrú òwò náà.
*Disadvantages of partnership # Àwọn àìláǹfààní àjọṣe*
(1) Unlimited liability # Àtijẹ̀bi aláìnígbèdéke: Àwọn alájọṣe ló ni àtijẹ̀bi gbèsè òwò àjọṣe náà títí dórí títóbi dúkìá wọn ní kíkún.
(2) Business is not a legal entity. # Òwò náà kì í ṣe ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin: kò lè peni lẹ́jọ́, a kò sì lè pè é lẹ́jọ́ ní orúkọ ara rẹ̀.
(3) Limited growth # Ìdàgbà onígbèdéke: Ìdàgbà àjọṣe náà ní gbèdéke lábẹ́ mímọ̀ọ́ṣe onídarí ti àwọn alájọṣe náà.
(4) Disagreement between partners can end the business. # Àìgbọ́rayé láàárín àwọn alájọṣe lè fòpin sí òwò náà.
(5) Risk of dissolution # Ewu ìtúká: Ikú, ìyawèrè àti ìjẹgbárun alájọṣe kan lè mú òwò náà wá sí òpin òjijì.
(6) Difficulty in management # Ìṣòro nínú ìdarí: Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé olúkúlùkù alájọṣe ni yóò fẹ́ wí tiẹ̀, àti-ṣèpinnu lè lọ́ra kó sì pẹ́.
(7) False records # Àwọn àkọsílẹ̀ èké: Apákan àwọn alájọṣe náà, pàápàá àwọn alájọṣe alákitiyan, le lo àkọsílẹ̀ èké láti jẹ àwọn àǹfààni kan lórí àwọn yòókù.
(8) Inability to raise sufficient capital # Àìlè kó ojúowó tító jọ
(9) Action of one partner is binding on others. # Ìgbésẹ̀ alájọṣe kan de àwọn yòókù. Alájọṣe kan lè fa àwọn yòókù rẹ̀ sínú ìṣòro látàrí àìkíyèsára rẹ̀. Nípa báyìí, òwò náà lè foríṣánpọ́n.
~Hakeem O. Adéníyan, 5/1/2022
+2347034251583.